15 Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́ṣùgbọ́n Olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbéṣẹ̀ rẹ̀.
16 Ọlọgbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibiṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra.
17 Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè,a sì kórìíra eléte ènìyàn:
18 Òpè jogún ìwà òmùgọ̀ṣùgbọ́n a dé ọlọgbọ́n ní adé ìmọ̀.
19 Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rereàti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo.
20 Kódà àwọn aládùúgbò o talákà kò fẹ́ràn rẹ̀ṣùgbọ́n, Ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀.
21 Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní.