27 Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ oríṣun ìyè,tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.
28 Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo Ọba,ṣùgbọ́n láì sí ìjòyè, Ọba á parun.
29 Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀,ṣùgbọ́n onínú fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.
30 Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara,ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.
31 Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hànṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.
32 Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀,kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.
33 Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóyekódà láàrin àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun.