3 Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàsán fún ẹ̀yìn rẹ̀,ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.
4 Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóníṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá.
5 Ẹlẹ́rìí tí ń sòótọ́ kì í tan niṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde.
6 Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.
7 Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.
8 Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà an wọnṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ asìwèrè ni ìtànjẹ.
9 Aláìgbọ́n ń ṣẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ṣùgbọ́n láàrin àwọn olódodo ni a ti rí ojú rere.