31 Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hànṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.
32 Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀,kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.
33 Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóyekódà láàrin àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun.
34 Ododo a máa gbé orílẹ̀ èdè ga,ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ.
35 Ọba a máa ní inú dídùn sí ìránṣẹ́ tí ó gbọ́nṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ wá sórí ìránṣẹ́ adójútini.