6 Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.
7 Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.
8 Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà an wọnṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ asìwèrè ni ìtànjẹ.
9 Aláìgbọ́n ń ṣẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ṣùgbọ́n láàrin àwọn olódodo ni a ti rí ojú rere.
10 Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀kò sì sí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.
11 A ó pa ilé ènìyàn búburú runṢùgbọ́n àgọ́ Olódodo yóò máa gbèrú síi.
12 Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn,ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa já sí ikú.