8 Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà an wọnṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ asìwèrè ni ìtànjẹ.
9 Aláìgbọ́n ń ṣẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ṣùgbọ́n láàrin àwọn olódodo ni a ti rí ojú rere.
10 Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀kò sì sí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.
11 A ó pa ilé ènìyàn búburú runṢùgbọ́n àgọ́ Olódodo yóò máa gbèrú síi.
12 Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn,ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa já sí ikú.
13 Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìnín, ọkàn leè máa kérora;ayọ̀ sì leè yọrí sí ìbànújẹ́.
14 A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀Ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀.