27 Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè.
28 Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wòṣùgbọ́n ẹnu ènìyàn búburú ń tú ibi jáde.
29 Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburúṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.
30 Ojú tó túká máa ń mú ayọ̀ wá fún ọkàn,ìròyìn ayọ̀ sì ń mú ìlera wá sínú egungun.
31 Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè,yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n.
32 Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀,Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ síi.
33 Ìbẹ̀rù Olúwa kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n,Ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.