9 Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburúṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.
10 Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an,ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.
11 Ikú àti ìparun sí sílẹ̀ níwájú Olúwamélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn.
12 Ẹlẹ́gàn kórìíra ìbáwí:kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.
13 Inú dídùn máa ń mú kí ojú túkáṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ọkàn máa ń pa ẹ̀mí run.
14 Ọkàn olóye ń wá ìmọ̀ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń fẹ́ ìwà òmùgọ̀ bí ẹní jẹun.
15 Gbogbo ọjọ́ àwọn olùpọ́njú jẹ́ ibi,ṣùgbọ́n ọkàn tí ń dunnú a máa Jàṣè ṣáá.