23 Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá:nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láì sí ewu.
24 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ;kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
25 Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n;bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ síi.
26 Ẹni tí ó já baba rẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jádeó jẹ́ adójútini ọmọ.
27 Yéé tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ tí í mú ni ṣìnà ọmọ mi,ìwọ kì yóò sì sìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìmọ̀.
28 Ajẹ́rìí tí ó bàjẹ́ máa ń kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mi.
29 A ti pèṣè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn;àti pàṣán fún ẹ̀yìn aláìgbọ́n.