19 Olófòófó dalẹ̀ àsírínítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ jù.
20 Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀,ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.
21 Ogún tí a kó jọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.
22 Má ṣe wí pé, “N ó ṣẹ̀ṣan àṣìṣe rẹ yìí fún ọ”Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là.
23 Olúwa kórìíra òdiwọ̀n èké.Òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.
24 Olúwa ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyànBáwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni?
25 Ìdẹkùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíánígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.