22 Má ṣe wí pé, “N ó ṣẹ̀ṣan àṣìṣe rẹ yìí fún ọ”Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là.
23 Olúwa kórìíra òdiwọ̀n èké.Òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.
24 Olúwa ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyànBáwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni?
25 Ìdẹkùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíánígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.
26 Ọlọgbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká;Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.
27 Àtùpà Olúwa ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàna máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú
28 Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́,nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.