4 Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹnítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.
5 Ètè ọkàn ènìyàn dàbí, omi jínjìn;ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.
6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń wí oore wọn jáde,ṣùgbọ́nn kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòótọ́.
7 Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkùìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.
8 Nígbà tí ọba bá jókóò sórí ilẹ̀ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.
9 Táni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́,mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?
10 Ìdíwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ Olúwa kórìíra méjèèjì.