7 Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkùìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.
8 Nígbà tí ọba bá jókóò sórí ilẹ̀ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.
9 Táni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́,mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?
10 Ìdíwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ Olúwa kórìíra méjèèjì.
11 Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.
12 Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran Olúwa ni ó dá méjèèjì.
13 Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di talákàmá ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.