17 Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di talákà:ẹni tí ó fẹ́ ọtí-wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀.
18 Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó-ìràpadà fún olódodo,àti olùrékọjá fún ẹni dídúró-ṣinṣin.
19 Ó sàn láti jókòó ní ihà ju pẹ̀lúoníjà obìnrin àti òṣónú lọ.
20 Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n;ṣùgbọ́n ènìyàn aṣiwèrè (òmùgọ̀) jẹ ẹ́ run.
21 Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè,òdodo, àti ọlá.
22 Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára,ó sì bi ibi-gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú.
23 Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́,ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu.