4 Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀?Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀?Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ?Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀?Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀?Sọ fún mi bí o bá mọ̀.
5 “Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù;oun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn
6 Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́.
7 “Ohun méjì ni mo ń bèèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa;má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú:
8 Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi;má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀,ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan,
9 Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹkí ń sì wí pé, ‘Ta ni Olúwa?’Tàbí kí ń di òtòsì kí ń sì jalèkí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.
10 “Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò ṣẹ́ èpè lé ọ. Ìwọ yóò sì jìyà rẹ̀.