1 Ọmọ mi, fiyè sí ọgbọ́n ọ̀n mi tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ àròjinlẹ̀mi
2 kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́rakí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.
3 Nítorí ètè alágbèrè aṣẹ́wó obìnrin a máa ṣun oyin,ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ
4 ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín, ó korò ju òróòro lọó mú bí idà olójú méjì.
5 Ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikúìgbéṣẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú.
6 Kò tilẹ̀ ronú nípa ọ̀nà ìyèọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.
7 Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ tẹ́tí sí mimá ṣe yàgò kúrò nínú àwọn nǹkan tí mo sọ