14 Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátapátaní àárin gbogbo àwùjọ ènìyàn.”
15 Mu omi láti inú un kànga tìrẹOmi tí ń ṣàn láti inú kànga rẹ.
16 Ó ha yẹ kí omi ìṣun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nààti odò tí ń sàn lọ sí àárin ọjà?
17 Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan,má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjòjì láéláé.
18 Ǹjẹ́, kí oríṣun rẹ di àbùkù fún;kí ó sì yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.
19 Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọJẹ́ kí ọmú rẹ̀ tẹ́ ọ lọ́rùn nígbà gbogbojẹ́ kí ìfẹ́ rẹ̀ máa fà ọ́ títí láéláé
20 Ọmọ mi, èéṣe tí ìfẹ́ aṣẹ́wó fi ń fà ọ́tí ìwọ sì ń dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?