5 Ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikúìgbéṣẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú.
6 Kò tilẹ̀ ronú nípa ọ̀nà ìyèọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.
7 Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ tẹ́tí sí mimá ṣe yàgò kúrò nínú àwọn nǹkan tí mo sọ
8 Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà síi dáadáamá ṣe súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀
9 àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo agbára rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn
10 kí àwọn àjòjì ó má baà fi ọrọ̀ rẹ ṣara rindinkí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.
11 Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora,nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán