9 àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo agbára rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn
10 kí àwọn àjòjì ó má baà fi ọrọ̀ rẹ ṣara rindinkí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.
11 Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora,nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán
12 Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó!Ọkàn mi ṣe wá kóòríra ìbáwí!
13 N kò gbọ́ràn sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu,tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.
14 Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátapátaní àárin gbogbo àwùjọ ènìyàn.”
15 Mu omi láti inú un kànga tìrẹOmi tí ń ṣàn láti inú kànga rẹ.