3 Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹunkọ wọ́n sí inú ọkàn rẹ.
4 Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,”sì pe òye ní ìbátan rẹ;
5 wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè,kúrò lọ́wọ́ ìyàwó onírìnkurìn àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀.
6 Ní ojú fèrèsé ilé è mimo wo ìta láti ojú ù fèrèsé.
7 Mo rí i láàrin àwọn aláìmọ́kanmo sì kíyèsí láàrin àwọn ọ̀dọ́kùnrin,ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.
8 Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbérè obìnrin náà,ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀
9 ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀,bí òkùnkùn ṣẹ ń bo ni lára.