11 Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùnọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.
12 Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè:bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”
13 Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo;ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláì ní ìmọ̀.
14 Ó jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀lórí ìjòkó níbi tí ó ga jù láàrin ìlú,
15 ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ,tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.
16 “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!”Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.
17 “Omi tí a jí mu dùnoúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”