17 ó sì gbé oúnjẹ aládùn tí ó sè ati àkàrà tí ó tọ́jú fún Jakọbu ọmọ rẹ̀.
18 Ni Jakọbu bá tọ baba rẹ̀ lọ, ó pè é, ó ní, “Baba mi,” Baba rẹ̀ bá dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi, ìwọ ta ni?”
19 Jakọbu dá baba rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni, mo ti ṣe bí o ti wí, dìde jókòó, kí o sì jẹ ninu ẹran ìgbẹ́ tí mo pa, kí o lè súre fún mi.”
20 Ṣugbọn Isaaki bi í léèrè pé, “O ti ṣe é tí o fi rí ẹran pa kíákíá bẹ́ẹ̀ ọmọ mi?” Jakọbu dáhùn pé “OLUWA Ọlọrun rẹ ni ó ṣe ọ̀nà mi ní rere.”
21 Isaaki bá wí tìfura-tìfura pé, “Súnmọ́ mi, kí n fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Esau ọmọ mi ni ọ́ lóòótọ́.”
22 Jakọbu bá súnmọ́ Isaaki baba rẹ̀, baba rẹ̀ fọwọ́ pa á lára, ó wí pé, “Ọwọ́ Esau ni ọwọ́ yìí, ṣugbọn ohùn Jakọbu ni ohùn yìí.”
23 Kò sì dá Jakọbu mọ̀, nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ ní irun bíi ti Esau ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó bá súre fún un.