35 Ṣugbọn Isaaki dáhùn pé, “Àbúrò rẹ ti wá pẹlu ẹ̀tàn, ó sì ti gba ìre rẹ lọ.”
36 Esau bá dáhùn pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ̀ nítòótọ́. Ó di ìgbà keji tí yóo fi èrú gba ohun tíí ṣe tèmi. Ó ti kọ́kọ́ gba ipò àgbà lọ́wọ́ mi, ó tún wá jí ìre mi gbà lọ.” Esau bá bèèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Ṣé o kò wá fi ẹyọ ìre kan pamọ́ fún mi ni?”
37 Isaaki dá a lóhùn, ó ní, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ni mo sì ti fún un láti fi ṣe iranṣẹ, mo ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọkà ati ọtí waini. Kí ló tún wá kù tí mo lè ṣe fún ọ, ọmọ mi?”
38 Esau bẹ̀rẹ̀ sí bẹ baba rẹ̀ pé, “Ṣé ìre kan ṣoṣo ni o ní lẹ́nu ni, baba mi? Áà! Súre fún èmi náà, baba mi.” Esau bá bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.
39 Nígbà náà ni Isaaki, baba rẹ̀, dá a lóhùn, ó ní,“Níbi tí ilẹ̀ kò ti lọ́ràá ni o óo máa gbé,níbi tí kò sí ìrì ọ̀run.
40 Pẹlu idà rẹ ni o óo fi wà láàyè, arakunrin rẹ ni o óo sì máa sìn,ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, o óo já ara rẹ gbà,o óo sì bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.”
41 Nítorí irú ìre tí baba wọn sú fún Esau yìí ni Esau ṣe kórìíra Jakọbu. Esau dá ara rẹ̀ lọ́kàn le ó ní, “Ìgbà mélòó ni ó kù tí baba wa yóo fi kú? Bí ó bá ti kú ni n óo pa Jakọbu, arakunrin mi.”