6 Esau rí i pé Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán an lọ sí Padani-aramu kí ó lọ fẹ́ iyawo, ati pé nígbà tí ó ń súre fún un, ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ fẹ́ ninu àwọn ọmọbinrin ará Kenaani.
7 Ó sì tún rí i pé Jakọbu gbọ́ ti baba ati ìyá rẹ̀, ó lọ sí Padani-aramu bí wọ́n ti sọ,
8 ati pé inú Isaaki, baba wọn kò dùn sí i pé kí wọn fẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kenaani níyàwó.
9 Nítorí náà Esau lọ sọ́dọ̀ Iṣimaeli ọmọ Abrahamu, ó sì fẹ́ Mahalati ọmọ rẹ̀, tíí ṣe arabinrin Nebaiotu, ó fi kún àwọn aya tí ó ti ní.
10 Jakọbu kúrò ní Beeriṣeba, ó ń lọ sí Harani.
11 Nígbà tí ó dé ibìkan tí ó rí i pé ilẹ̀ ti ń ṣú, ó gbé ọ̀kan ninu àwọn òkúta tí ó wà níbẹ̀, ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn.
12 Nígbà tí ó sùn, ó lá àlá kan, ó rí àkàsọ̀ kan lójú àlá, wọ́n gbé e kalẹ̀, orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run. Ó wá rí i tí àwọn angẹli Ọlọrun ń gùn ún lọ sókè sódò.