8 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbúròó OLUWA Ọlọrun tí ń rìn ninu ọgbà. Wọ́n bá sá pamọ́ sí ààrin àwọn igi ọgbà.
9 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun pe ọkunrin náà, ó bi í pé, “Níbo ni o wà?”
10 Ó dá Ọlọrun lóhùn, ó ní, “Nígbà tí mo gbúròó rẹ ninu ọgbà, ẹ̀rù bà mí, mo bá farapamọ́ nítorí pé ìhòòhò ni mo wà.”
11 Ọlọrun bi í pé, “Ta ló sọ fún ọ pé ìhòòhò ni o wà? Àbí o ti jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ?”
12 Ọkunrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin tí o fi tì mí ni ó fún mi ninu èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”
13 OLUWA Ọlọrun bi obinrin náà pé, “Irú kí ni o dánwò yìí?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Ejò ni ó tàn mí tí mo fi jẹ ẹ́.”
14 OLUWA Ọlọrun bá sọ fún ejò náà pé,“Nítorí ohun tí o ṣe yìí,o di ẹni ìfibú jùlọ láàrin gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko.Àyà rẹ ni o óo máa fi wọ́ káàkiri,erùpẹ̀ ni o óo sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.