7 Josẹfu rí àwọn arakunrin rẹ̀, ó sì mọ̀ wọ́n, ṣugbọn ó bá wọn sọ̀rọ̀ pẹlu ohùn líle bí ẹni pé kò mọ̀ wọ́n rí, ó ní, “Níbo ni ẹ ti wá?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni, oúnjẹ ni a wá rà.”
8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Josẹfu mọ̀ dájú pé àwọn arakunrin òun ni wọ́n, wọn kò mọ̀ ọ́n.
9 Josẹfu wá ranti àlá rẹ̀ tí ó lá nípa wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Amí ni yín, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.”
10 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o, oluwa mi, oúnjẹ ni àwa iranṣẹ rẹ wá rà.
11 Ọmọ baba kan náà ni gbogbo wa, olóòótọ́ eniyan sì ni wá, a kì í ṣe amí.”
12 Josẹfu tún sọ fún wọn pé, “N kò gbà, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.”
13 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, wọ́n ní, “Ọkunrin mejila ni àwa iranṣẹ rẹ, tí a jẹ́ ọmọ baba kan náà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa wà lọ́dọ̀ baba wa nílé, ọ̀kan yòókù ti kú.”