20 Aṣeri yóo máa rí oúnjẹ dáradára mú jáde ninu oko rẹ̀,oúnjẹ ọlọ́lá ni yóo máa ti inú oko rẹ̀ jáde.
21 Nafutali dàbí àgbọ̀nrín tí ń sáré káàkiri,tí ó sì ní àwọn ọmọ tí ó lẹ́wà.
22 Josẹfu dàbí igi eléso tí ó wà lẹ́bàá odò,àwọn ẹ̀ka rẹ̀ nà mọ́ ara ògiri.
23 Àwọn tafàtafà gbógun tì í kíkankíkan,wọ́n ń ta á lọ́fà, wọ́n sì ń dà á láàmú gidigidi,
24 sibẹsibẹ ọrùn rẹ̀ kò mì,apá rẹ̀ sì ń lágbára sí i.Agbára Ọlọrun Jakọbu ni ó fún apá rẹ̀ ní okun,(ní orúkọ Olùṣọ́-aguntan náà,tí í ṣe Àpáta ààbò Israẹli),
25 Ọlọrun baba rẹ yóo ràn ọ́ lọ́wọ́.Ọlọrun Olodumare yóo rọ òjò ibukun sórí rẹ láti òkè ọ̀run wá,yóo sì fún ọ ní ibukun omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀,ati ọpọlọpọ ọmọ ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn.
26 Ibukun àwọn baba rẹ ju ti àwọn òkè ayérayé lọ,kí ibukun àwọn òkè ayérayé wá sórí Josẹfu,ẹni tí wọ́n yà ní ipá lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀.