1 Ọlọrun súre fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.
2 Gbogbo ẹranko tí ó wà láyé, gbogbo ẹyẹ, gbogbo ẹja tí ń bẹ ninu omi, ati gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri ni yóo máa bẹ̀rù yín, ìkáwọ́ yín ni mo fi gbogbo wọn sí.
3 Gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ni yóo jẹ́ oúnjẹ fún yín, bí mo ti fún yín ní gbogbo ewéko, bẹ́ẹ̀ náà ni mo fún yín ní ohun gbogbo.
4 Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran ti òun ti ẹ̀jẹ̀, nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ìyè wà.