14 Nítorí náà, Ọlọrun rán àjàkálẹ̀ àrùn sórí ilẹ̀ Israẹli, àwọn tí wọ́n kú sì jẹ́ ẹgbaa marundinlogoji (70,000) eniyan.
15 Ọlọrun rán angẹli kan pé kí ó lọ pa Jerusalẹmu run; ṣugbọn bí ó ti fẹ́ pa á run, OLUWA rí i, ó sì yí ọkàn pada, ó wí fún apanirun náà pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, dáwọ́ dúró.” Angẹli OLUWA náà bá dúró níbi ìpakà Onani ará Jebusi.
16 Dafidi rí angẹli náà tí ó dúró ní agbede meji ayé ati ọ̀run, tí ó na idà ọwọ́ rẹ̀ sí orí Jerusalẹmu. Dafidi ati àwọn ìjòyè àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ bá dojúbolẹ̀.
17 Dafidi bá sọ fún Ọlọrun pé, “Ṣebí èmi ni mo pàṣẹ pé kí wọ́n lọ ka àwọn eniyan? Èmi ni mo ṣẹ̀, tí mo sì ṣe nǹkan burúkú. Kí ni àwọn aguntan wọnyi ṣe? OLUWA, Ọlọrun mi, mo bẹ̀ ọ́, èmi ati ilé baba mi ni kí o jẹ níyà, má jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí wá sórí àwọn eniyan rẹ.”
18 Angẹli OLUWA bá pàṣẹ fún Gadi pé kí ó lọ sọ fún Dafidi pé kí ó lọ tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA ní ibi ìpakà Onani ará Jebusi.
19 Dafidi bá dìde gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gadi, tí ó sọ ní orúkọ OLÚWA.
20 Onani ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mẹrin wà níbi tí wọ́n ti ń pakà. Nígbà tí wọ́n rí angẹli náà, wọ́n sápamọ́.