Kronika Kinni 26:25-31 BM

25 Ninu àwọn arakunrin Ṣebueli, láti ìdílé Elieseri, a yan Rehabaya ọmọ Elieseri, Jeṣaaya ọmọ Rehabaya, Joramu ọmọ Jeṣaaya, Sikiri ọmọ Joramu ati Ṣelomiti ọmọ Sikiri.

26 Ṣelomiti yìí ati àwọn arakunrin rẹ̀ ni wọ́n ń bojútó àwọn ẹ̀bùn tí Dafidi ọba, ati ti àwọn olórí àwọn ìdílé, ati èyí tí àwọn olórí ọmọ ogun ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un, ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.

27 Ninu àwọn ìkógun tí wọ́n kó lójú ogun, wọ́n ya àwọn ẹ̀bùn kan sọ́tọ̀ fún ìtọ́jú ilé OLUWA.

28 Ṣelomiti ati àwọn arakunrin rẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ìtọ́jú ẹ̀bùn tí àwọn eniyan bá mú wá, ati àwọn ohun tí wolii Samuẹli, ati Saulu ọba, ati Abineri, ọmọ Neri, ati Joabu, ọmọ Seruaya, ti yà sọ́tọ̀ ninu ilé OLUWA.

29 Ninu ìdílé Iṣari, Kenanaya ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n yàn ní alákòóso ati onídàájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli.

30 Ninu ìdílé Heburoni, Haṣabaya ati ẹẹdẹgbẹsan (1,700) àwọn arakunrin rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ alágbára ni wọ́n ń bojútó àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ OLUWA ati iṣẹ́ ọba,

31 Ninu ìdílé Heburoni, Jerija ni baba ńlá gbogbo wọn. (Ní ogoji ọdún tí Dafidi dé orí oyè, wọ́n ṣe ìwádìí nípa ìran Heburoni, wọ́n sì rí àwọn ọkunrin tí wọ́n lágbára ninu ìran wọn ní Jaseri ní agbègbè Gileadi).