7 Orúkọ wọn ni: Otini, Refaeli, Obedi, ati Elisabadi, ati àwọn arakunrin wọn, Elihu ati Semakaya, tí wọ́n jẹ́ alágbára eniyan.
8 Gbogbo àwọn arọmọdọmọ Obedi Edomu, ati àwọn ọmọ wọn, pẹlu àwọn arakunrin wọn, tí wọ́n yẹ láti ṣiṣẹ́ jẹ́ mejilelọgọta.
9 Àwọn ọmọ Meṣelemaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí wọ́n lágbára jẹ́ mejidinlogun.
10 Hosa, láti inú ìran Merari bí ọmọkunrin mẹrin: Ṣimiri (ni baba rẹ̀ fi ṣe olórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe òun ni àkọ́bí);
11 lẹ́yìn rẹ̀ Hilikaya, Tebalaya ati Sakaraya. Gbogbo àwọn ọmọ Hosa ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mẹtala.
12 Gbogbo àwọn aṣọ́nà tẹmpili ni a pín sí ẹgbẹẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. A pín iṣẹ́ fún àwọn náà gẹ́gẹ́ bí a ti pín iṣẹ́ fún àwọn arakunrin wọn yòókù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA.
13 Gègé ni wọ́n ṣẹ́ fún ìdílé kọ̀ọ̀kan, láti mọ ẹnu ọ̀nà tí wọn yóo máa ṣọ́, wọn ìbáà jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ, wọn ìbáà sì jẹ́ eniyan pataki.