9 Àwọn ọmọ Meṣelemaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí wọ́n lágbára jẹ́ mejidinlogun.
10 Hosa, láti inú ìran Merari bí ọmọkunrin mẹrin: Ṣimiri (ni baba rẹ̀ fi ṣe olórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe òun ni àkọ́bí);
11 lẹ́yìn rẹ̀ Hilikaya, Tebalaya ati Sakaraya. Gbogbo àwọn ọmọ Hosa ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mẹtala.
12 Gbogbo àwọn aṣọ́nà tẹmpili ni a pín sí ẹgbẹẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. A pín iṣẹ́ fún àwọn náà gẹ́gẹ́ bí a ti pín iṣẹ́ fún àwọn arakunrin wọn yòókù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA.
13 Gègé ni wọ́n ṣẹ́ fún ìdílé kọ̀ọ̀kan, láti mọ ẹnu ọ̀nà tí wọn yóo máa ṣọ́, wọn ìbáà jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ, wọn ìbáà sì jẹ́ eniyan pataki.
14 Ṣelemaya ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn. Sakaraya, ọmọ rẹ̀, olùdámọ̀ràn tí ó mòye, ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà àríwá.
15 Obedi Edomu ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà gúsù; àwọn ọmọ rẹ̀ ni a sì yàn láti máa ṣọ́ ilé ìṣúra.