3 Àwọn ọmọ Etamu ni: Jesireeli, Iṣima, ati Idibaṣi. Orúkọ arabinrin wọn ni Haseleliponi.
4 Penueli ni baba Gedori. Eseri bí Huṣa. Àwọn ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efurata, tí ó jẹ́ baba Bẹtilẹhẹmu.
5 Aṣuri, baba Tekoa, ní aya meji: Hela ati Naara.
6 Naara bí ọmọ mẹrin fún un: Ahusamu, Heferi, Temeni, ati Haahaṣitari.
7 Hela bí ọmọ mẹta fún un: Sereti, Iṣari, ati Etinani.
8 Kosi ni baba Anubi ati Sobeba. Òun ni baba ńlá àwọn ìdílé Ahaheli, ọmọ Harumu.
9 Ọkunrin kan, tí à ń pè ní Jabesi, jẹ́ eniyan pataki ju àwọn arakunrin rẹ̀ lọ. Ìyá rẹ̀ sọ ọ́ ní orúkọ yìí nítorí ìrora pupọ tí ó ní nígbà tí ó bí i.