1 A si mu Solomoni, ọmọ Dafidi, lagbara lori ijọba rẹ̀, Oluwa Ọlọrun rẹ̀ si wà pẹlu rẹ̀, o si gbé e ga gidigidi.
2 Solomoni si sọ fun gbogbo Israeli, fun awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati fun awọn onidajọ, ati fun gbogbo awọn bãlẹ ni gbogbo Israeli, awọn olori awọn baba.
3 Solomoni ati gbogbo awọn ijọ enia pẹlu rẹ̀, lọ si ibi giga ti o wà ni Gibeoni; nitori nibẹ ni agọ ajọ enia Ọlọrun gbe wà, ti Mose, iranṣẹ Oluwa ti pa ni aginju.
4 Apoti-ẹri Ọlọrun ni Dafidi ti gbé lati Kirjat-jearimu wá si ibi ti Dafidi ti pese silẹ fun u, nitoriti o ti pa agọ kan silẹ fun u ni Jerusalemu.
5 Ṣugbọn pẹpẹ idẹ ti Besaleeli, ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ṣe, wà nibẹ niwaju agọ Oluwa: Solomoni ati ijọ enia si wá a ri.
6 Solomoni si lọ si ibi pẹpẹ idẹ niwaju Oluwa, ti o ti wà nibi agọ ajọ, o si rú ẹgbẹrun ẹbọ-sisun lori rẹ̀.
7 Li oru na li Oluwa fi ara hàn Solomoni, o si wi fun u pe, Bère ohun ti emi o fi fun ọ.