21 On si wipe, Emi o jade lọ, emi o si di ẹmi eke li ẹnu gbogbo awọn woli rẹ̀. Oluwa si wipe, Iwọ o tàn a, iwọ o si bori pẹlu: jade lọ, ki o si ṣe bẹ̃ na.
22 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, Oluwa ti fi ẹmi eke si ẹnu gbogbo awọn woli rẹ wọnyi, Oluwa si ti sọ ibi si ọ.
23 Nigbana ni Sedekiah, ọmọ Kenaana, sunmọ ọ, o si lù Mikaiah li ẹ̀rẹkẹ, o si wipe, Ọ̀na wo li ẹmi Oluwa gbà kọja lọ kuro lọdọ mi lati ba ọ sọ̀rọ.
24 Mikaiah si wipe, Kiyesi i, iwọ o ri i li ọjọ na, nigbati iwọ o wọ inu iyẹwu de inu iyẹwu lọ ifi ara rẹ pamọ́,
25 Nigbana ni ọba Israeli wipe, Ẹ mu Mikaiah, ki ẹ si mu u pada sọdọ Amoni, olori ilu, ati sọdọ Joaṣi, ọmọ ọba.
26 Ki ẹ si wipe, Bayi li ọba wi, ẹ fi eleyi sinu tubu, ki ẹ si fi ọnjẹ ipọnju ati omi ipọnju bọ́ ọ, titi emi o fi pada bọ̀ li alafia.
27 Mikaiah si wipe, Ni pipada bi iwọ ba pada bọ̀ li alafia, njẹ Oluwa kò ti ọdọ mi sọ̀rọ. O si wipe, Ẹ gbọ́, ẹnyin enia gbogbo!