31 O si ṣe, nigbati awọn olori kẹkẹ́ ri Jehoṣafati, ni nwọn wipe eyi li ọba Israeli, nitorina nwọn yi i ka lati ba a jà: ṣugbọn Jehoṣafati kigbe, Oluwa si ràn a lọwọ: Ọlọrun si yi wọn pada kuro lọdọ rẹ̀.
32 O si ṣe, bi awọn olori kẹkẹ́ ti woye pe kì iṣe ọba Israeli, nwọn yipada kuro lẹhin rẹ̀.
33 Ọkunrin kan si fa ọrun rẹ̀ laipete, o si ta ọba Israeli lãrin ipade ẹwu-irin, o si wi fun olutọju kẹkẹ́ rẹ̀ pe, Yi ọwọ rẹ pada, ki o mu mi jade kuro loju ìja; nitoriti mo gbọgbẹ́.
34 Ija na si pọ̀ li ọjọ na: pẹlupẹlu ọba Israeli duro ninu kẹkẹ́ rẹ̀ kọju si awọn ara Siria titi di aṣãlẹ: o si kú li akokò ìwọ õrun.