9 Ani lati pèse ìti-igi lọpọlọpọ silẹ fun mi: nitori ile na ti emi mura lati kọ́ tobi, o si ya ni lẹnu.
10 Si wò o, emi o fi fun ilo awọn akégi, ti nké ìti-igi, lọwọ awọn ọmọ-ọdọ rẹ, ẹgbãwa òṣuwọn alikama fun onjẹ, ati ẹgbãwa òṣuwọn barli ati ẹgbãwa bati ọti-waini, ati ẹgbãwa bati ororo.
11 Nigbana ni Huramu, ọba Tire, kọwe dahùn o si ranṣẹ si Solomoni pe, Nitori ti Oluwa fẹran awọn enia rẹ̀ li o ṣe fi ọ jọba lori wọn.
12 Huramu si wipe, Alabukún fun li Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o da ọrun on aiye, ẹniti o fun Dafidi ọba ni ọlọgbọ́n ọmọ, ti o mọ̀ ọgbọ́n ati oye, ti o le kọ́ ile fun Oluwa, ati ile fun ijọba rẹ̀.
13 Njẹ nisisiyi emi rán ọkunrin ọlọgbọ́n kan, ti o mọ̀ oye, ani Huramu-Abi,
14 Ọmọ obinrin kan ninu awọn ọmọbinrin Dani: baba rẹ̀ si ṣe ọkunrin ara Tire ti o gbọ́ngbọn ati ṣiṣẹ ni wura, ati ni fadakà, ni idẹ, ni irin, ni okuta, ati ni ìti-igi, ni èse-aluko, ni alaró, ati ni ọ̀gbọ daradara, ati òdodó, lati gbẹ́ oniruru ohun gbigbẹ́ pẹlu, ati lati ṣe awari ìmọ ẹrọ gbogbo ti a o fi fun u ṣe, pẹlu awọn ọlọgbọ́n rẹ, ati pẹlu awọn ọlọgbọ́n oluwa mi Dafidi, baba rẹ.
15 Njẹ nitorina alikama ati ọkà barli, ororo, ati ọti-waini na ti oluwa mi ti sọ, jẹ ki o fi ranṣẹ si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀.