24 Nitori ogun awọn ara Siria dé pẹlu ẹgbẹ diẹ, Oluwa si fi ogun ti o pọ̀ gidigidi le wọn lọwọ, nitoriti nwọn kọ̀ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ. Bẹ̃ni nwọn si ṣe idajọ Joaṣi.
25 Nigbati nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀, (nwọn sa ti fi i silẹ ninu àrun nla) awọn iranṣẹ rẹ̀ si di rikiṣi si i, nitori ẹ̀jẹ awọn ọmọ Jehoiada alufa, nwọn si pa a lori akete rẹ̀, o si kú: nwọn si sìn i ni ilu Dafidi, ṣugbọn nwọn kò sìn i ni iboji awọn ọba.
26 Wọnyi li awọn ti o di rikiṣi si i, Sabadi, ọmọ Simeati, obinrin ara Ammoni, ati Jehosabadi, ọmọ Ṣimriti, obinrin ara Moabu.
27 Njẹ niti awọn ọmọ rẹ̀, ati titobi owo-ọba, ti a fi le e lori, ati atunṣe ile Ọlọrun, kiyesi i, a kọ wọn sinu itan iwe awọn ọba. Amasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.