2. Kro 29:16-22 YCE

16 Awọn alufa si wọ inu ile Oluwa lọhun lọ, lati gbá a mọ́, nwọn si mu gbogbo ẽri ti nwọn ri ninu tempili Oluwa jade si inu agbala ile Oluwa. Awọn ọmọ Lefi si kó o, nwọn si rù u jade gbangba lọ si odò Kidroni.

17 Njẹ nwọn bẹ̀rẹ li ọjọ kini oṣù kini, lati yà a si mimọ́, ati li ọjọ kẹjọ oṣù na, nwọn de iloro Oluwa: bẹ̃ni nwọn fi ọjọ mẹjọ yà ile Oluwa si mimọ́; ati li ọjọ kẹrindilogun oṣù kini na, nwọn pari rẹ̀.

18 Nigbana ni nwọn wọle tọ̀ Hesekiah ọba, nwọn si wipe: Awa ti gbá ile Oluwa mọ́, ati pẹpẹ ẹbọ sisun, pẹlu gbogbo ohun-elo rẹ̀, ati tabili akara-ifihan, pẹlu gbogbo ohun-elo rẹ̀.

19 Pẹlupẹlu gbogbo ohun-elo, ti Ahasi, ọba, ti sọ di alaimọ́ ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, li akokò ijọba rẹ̀, li awa ti pese ti awa si ti yà si mimọ́, si kiyesi i, nwọn mbẹ niwaju pẹpẹ Oluwa.

20 Nigbana ni Hesekiah, ọba, dide ni kutukutu; o si kó awọn olori ilu jọ, o si gòke lọ sinu ile Oluwa.

21 Nwọn si mu akọ-malu meje wá, ati àgbo meje, ati ọdọ-agutan meje, ati obukọ meje fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ijọba na, ati fun ibi mimọ́ na, ati fun Juda. O si paṣẹ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, lati fi wọn rubọ lori pẹpẹ Oluwa.

22 Bẹ̃ni awọn alufa pa awọn akọ-malu na, nwọn si gba ẹ̀jẹ na, nwọn si fi wọ́n ara pẹpẹ: bẹ̃ gẹgẹ nigbati nwọn pa awọn àgbo, nwọn fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ; nwọn pa awọn ọdọ-agutan pẹlu nwọn si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ.