28 Gbogbo ijọ enia na si wolẹ sìn, awọn akọrin, kọrin, ati awọn afunpè fun: gbogbo wọnyi si wà bẹ̃ titi ẹbọ sisun na fi pari tan.
29 Nigbati nwọn si ṣe ipari ẹbọ riru, ọba ati gbogbo awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ tẹ̀ ara wọn ba, nwọn si sìn.
30 Pẹlupẹlu Hesekiah ọba, ati awọn ijoye paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, lati fi ọ̀rọ Dafidi ati ti Asafu ariran, kọrin iyìn si Oluwa: nwọn si fi inu-didùn kọrin iyìn, nwọn si tẹri wọn ba, nwọn si sìn.
31 Nigbana ni Hesekiah dahùn, o si wipe, Nisisiyi, ọwọ nyin kún fun ẹ̀bun fun Oluwa, ẹ ṣunmọ ihin, ki ẹ si mu ẹbọ ati ọrẹ-ọpẹ wá sinu ile Oluwa. Ijọ ẹnia si mu ẹbọ ati ọrẹ-ọpẹ wá; ati olukuluku ti ọkàn rẹ̀ fẹ, mu ẹbọ sisun wá.
32 Iye ẹbọ sisun, ti ijọ enia mu wá, si jẹ ãdọrin akọ-malu, ati ọgọrun àgbo, ati igba ọdọ-agutan: gbogbo wọnyi si ni fun ẹbọ-sisun si Oluwa.
33 Awọn ohun ìyasi-mimọ́ si jẹ ẹgbẹta malu, ati ẹgbẹdogun agutan.
34 Ṣugbọn awọn alufa kò to, nwọn kò si le họ gbogbo awọn ẹran ẹbọ sisun na: nitorina awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi ràn wọn lọwọ, titi iṣẹ na fi pari, ati titi awọn alufa iyokù fi yà ara wọn si mimọ́: nitori awọn ọmọ Lefi ṣe olõtọ li ọkàn jù awọn alufa lọ lati yà ara wọn si mimọ́.