9 Nitori bi ẹnyin ba tun yipada si Oluwa, awọn arakunrin nyin, ati awọn ọmọ nyin, yio ri ãnu niwaju awọn ti o kó wọn ni ìgbekun lọ, ki nwọn ki o le tun pada wá si ilẹ yi: nitori Oluwa Ọlọrun nyin, oniyọ́nu ati alãnu ni, kì yio si yi oju rẹ̀ pada kuro lọdọ nyin, bi ẹnyin ba pada sọdọ rẹ̀.
10 Bẹ̃ li awọn onṣẹ na kọja lati ilu de ilu, ni ilẹ Efraimu ati Manasse titi de Sebuluni: ṣugbọn nwọn fi wọn rẹrin ẹlẹya, nwọn si gàn wọn.
11 Sibẹ omiran ninu awọn enia Aṣeri ati Manasse ati Sebuluni rẹ̀ ara wọn silẹ, nwọn si wá si Jerusalemu.
12 Ni Judah pẹlu, ọwọ Ọlọrun wà lati fun wọn li ọkàn kan lati pa ofin ọba mọ́ ati ti awọn ijoye, nipa ọ̀rọ Oluwa.
13 Ọ̀pọlọpọ enia si pejọ ni Jerusalemu, lati pa ajọ akara alaiwu mọ́ li oṣu keji, ijọ enia nlanla.
14 Nwọn si dide, nwọn si kó gbogbo pẹpẹ ti o wà ni Jerusalemu lọ, ati gbogbo pẹpẹ turari ni nwọn kó lọ, nwọn si dà wọn si odò Kidroni.
15 Nigbana ni nwọn pa ẹran irekọja na li ọjọ kẹrinla oṣù keji: oju si tì awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, nwọn si yà ara wọn si mimọ́, nwọn si mu ẹbọ sisun wá sinu ile Oluwa.