15 O si kó awọn àjeji ọlọrun ati ere kuro ni ile Oluwa, ati gbogbo pẹpẹ ti o ti tẹ́ lori òke ile Oluwa ati ni Jerusalemu, o si kó wọn danu kuro ni ilu.
16 O si tun pẹpẹ Oluwa ṣe, o si rú ẹbọ alafia ati ẹbọ ọpẹ lori rẹ̀, o si paṣẹ fun Juda lati ma sìn Oluwa Ọlọrun Israeli.
17 Sibẹ awọn enia nṣe irubọ ni ibi giga wọnni, kiki si Oluwa, Ọlọrun wọn nikan ni.
18 Ati iyokù iṣe Manasse, ati adura rẹ̀ si Ọlọrun rẹ̀, ati ọ̀rọ awọn ariran ti o ba a sọ̀rọ li orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli, kiye si i, o wà ninu iwe ọba Israeli.
19 Adura rẹ̀ na pẹlu, bi Ọlọrun ti gbọ́ ẹ̀bẹ rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ati irekọja rẹ̀ ati ibi ti o gbe kọ́ ibi giga wọnni ti o si gbé ere-oriṣa kalẹ, ati awọn ere yiyá, ki a to rẹ̀ ẹ silẹ, kiye si i, a kọ wọn sinu iwe itan Hosai.
20 Manasse si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i si ile on tikalarẹ̀: Amoni, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
21 Ẹni ọdun mejidilogun ni Amoni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun meji ni Jerusalemu.