2. Kro 35:9-15 YCE

9 Koniah ati Ṣemaiah ati Netaneeli, awọn arakunrin rẹ̀, ati Hasabiah ati Jehieli ati Josabadi, olori awọn ọmọ Lefi, si fun awọn ọmọ Lefi fun ẹbọ irekọja na ni ẹgbẹdọgbọn ọdọ-agutan, ati ẹ̃dẹgbẹta malu.

10 Bẹ̃li a si mura ìsin na, awọn alufa si duro ni ipò wọn, ati awọn ọmọ Lefi ni ipa iṣẹ wọn gẹgẹ bi aṣẹ ọba.

11 Awọn ọmọ Lefi si pa ẹran irekọja na, awọn alufa si wọ́n ẹ̀jẹ na lati ọwọ wọn wá, awọn ọmọ Lefi si bó wọn.

12 Nwọn si yà awọn ẹbọ-sisun sapakan, ki nwọn ki o le pin wọn funni gẹgẹ bi ipin idile awọn enia, lati rubọ si Oluwa, bi a ti kọ ọ ninu iwe Mose. Bẹ̃ni nwọn si ṣe awọn malu pelu.

13 Nwọn si fi iná sun irekọja na gẹgẹ bi ilana na: ṣugbọn awọn ẹbọ mimọ́ iyokù ni nwọn bọ̀ ninu ìkoko, ati ninu òdu ati ninu agbada, nwọn si pin i kankan fun gbogbo enia.

14 Lẹhin na nwọn mura silẹ fun ara wọn, ati fun awọn alufa; nitoriti awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, wà ni riru ẹbọ sisun ati ọ̀ra titi di alẹ; nitorina awọn ọmọ Lefi mura silẹ fun ara wọn ati fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni.

15 Awọn akọrin, awọn ọmọ Asafu duro ni ipò wọn, gẹgẹ bi ofin Dafidi, ati ti Asafu, ati ti Hemani, ati ti Jedutuni, ariran ọba; awọn adèna si duro ni olukuluku ẹnu-ọ̀na; nwọn kò gbọdọ lọ kuro li ọ̀na-iṣẹ wọn, nitoriti awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi, ti mura silẹ dè wọn.