1 NIGBANA ni awọn enia ilẹ na mu Jehoahasi, ọmọ Josiah, nwọn si fi i jọba ni ipò baba rẹ̀ ni Jerusalemu.
2 Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Jehoahasi, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba oṣu mẹta ni Jerusalemu.
3 Ọba Egipti si mu u kuro ni Jerusalemu, o si bù ọgọrun fadakà ati talenti wura kan fun ilẹ na.
4 Ọba Egipti si fi Eliakimu, arakunrin rẹ̀, jọba lori Juda ati Jerusalemu, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Jehoiakimu; Neko si mu Jehoahasi, arakunrin rẹ̀, o si mu u lọ si Egipti.
5 Ẹni ọdun mẹdọgbọn ni Jehoiakimu, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu; o si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀,
6 Nebukadnessari, ọba Babeli, gòke wá, o si dè e ni ẹ̀won, lati mu u lọ si Babeli.
7 Nebukadnessari kó ninu ohun-elo ile Oluwa lọ si Babeli pẹlu, o si fi wọn sinu ãfin rẹ̀ ni Babeli.