3 Aworan malu si wà labẹ rẹ̀ yi i kakiri, nwọn si lọ yi agbada nla na kakiri: igbọnwọ mẹwa yi i ka, ọwọ́ meji malu li a dà ni didà wọn kan.
4 O duro lori malu mejila wọnni, mẹta nwò iha ariwa, ati mẹta nwò iwọ-õrun, ati mẹta nwò gusu ati mẹta nwò iha ilà-orun: a si gbé agbada na ka ori wọn, gbogbo iha ẹhin wọn si wà ninu.
5 O si nipọn to ibu atẹlẹwọ, a si fi itanna lili ṣiṣẹ eti rẹ̀ gẹgẹ bi eti ago, o si gbà, o si da ẹgbẹdogun ìwọn bati duro.
6 O ṣe agbada mẹwa pẹlu, o si fi marun si apa ọtún, ati marun si apa òsi, lati wẹ̀ ninu wọn: iru nkan ti nwọn fi nrubọ sisun ni nwọn nwẹ̀ ninu wọn; ṣugbọn agbada na ni fun awọn alufa lati ma wẹ̀.
7 O si ṣe ọpa-fitila wura mẹwa gẹgẹ bi apẹrẹ wọn, o si fi wọn sinu tempili, marun li apa ọtún, ati marun li apa òsi.
8 O si ṣe tabili mẹwa, o si fi sinu tempili, marun li apa ọtún, ati marun li apa òsi. O si ṣe ọgọrun ọpọ́n wura.
9 O ṣe agbala awọn alufa pẹlu, ati agbala nla, ati ilẹkun fun agbala nla na, o si fi idẹ bo awẹ meji ilẹkun wọn.