12 Oluwa si fi ara hàn Solomoni li oru, o si wi fun u pe, Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi si ti yàn ihinyi fun ara mi, fun ile ẹbọ.
13 Bi mo ba sé ọrun ti kò ba si òjo, tabi bi emi ba paṣẹ fun eṣú lati jẹ ilẹ na run, tabi bi mo ba rán àjakalẹ-arun si ãrin awọn enia mi;
14 Bi awọn enia mi ti a npè orukọ mi mọ́, ba rẹ̀ ara wọn silẹ, ti nwọn ba si gbadura, ti nwọn ba si wá oju mi, ti nwọn ba si yipada kuro ninu ọ̀na buburu wọn; nigbana ni emi o gbọ́ lati ọrun wá, emi o si dari ẹ̀ṣẹ wọn jì, emi o si wò ilẹ wọn sàn.
15 Nisisiyi oju mi yio ṣí, eti mi yio si tẹ́ si adura ibi yi.
16 Njẹ nisisiyi emi ti yàn, emi si ti yà ile yi si mimọ́, ki orukọ mi ki o le ma wà nibẹ lailai: ati oju mi ati ọkàn mi yio ma wà nibẹ nigbagbogbo.
17 Ati iwọ, bi iwọ o ba rìn niwaju mi bi Dafidi, baba rẹ ti rìn, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo ti pa li aṣẹ fun ọ, bi iwọ o ba si ṣe akiyesi aṣẹ mi ati idajọ mi;
18 Nigbana ni emi o fi idi itẹ ijọba rẹ múlẹ̀, gẹgẹ bi emi ti ba Dafidi, baba rẹ dá majẹmu, wipe, a kì yio fẹ ẹnikan kù fun ọ ti yio ma ṣe akoso ni Israeli.