16 Njẹ nisisiyi emi ti yàn, emi si ti yà ile yi si mimọ́, ki orukọ mi ki o le ma wà nibẹ lailai: ati oju mi ati ọkàn mi yio ma wà nibẹ nigbagbogbo.
17 Ati iwọ, bi iwọ o ba rìn niwaju mi bi Dafidi, baba rẹ ti rìn, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo ti pa li aṣẹ fun ọ, bi iwọ o ba si ṣe akiyesi aṣẹ mi ati idajọ mi;
18 Nigbana ni emi o fi idi itẹ ijọba rẹ múlẹ̀, gẹgẹ bi emi ti ba Dafidi, baba rẹ dá majẹmu, wipe, a kì yio fẹ ẹnikan kù fun ọ ti yio ma ṣe akoso ni Israeli.
19 Ṣugbọn bi ẹnyin ba yipada, ti ẹ ba si kọ̀ aṣẹ mi ati ofin mi silẹ, ti emi ti gbé kalẹ niwaju nyin, ti ẹnyin ba si sin ọlọrun miran, ti ẹ si bọ wọn;
20 Nigbana ni emi o fà wọn tu ti-gbongbo-ti-gbongbo kuro ni ilẹ ti emi ti fi fun wọn; ati ile yi, ti emi ti yà si mimọ́ fun orukọ mi, li emi o ta nù kuro niwaju mi, emi o si sọ ọ di owe, ati ọ̀rọ-ẹgan larin gbogbo orilẹ-ède.
21 Ati ile yi, ti o ga, yio di ohun iyanu fun gbogbo ẹni ti o gba ibẹ kọja; tobẹ̃ ti yio si wipe, ẽṣe ti Oluwa fi ṣe bayi si ilẹ yi, ati si ile yi?
22 A o si dahùn wipe, Nitori ti nwọn kọ̀ Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, Ẹniti o mu wọn ti ilẹ Egipti jade wá, ti nwọn si di ọlọrun miran mu, ti nwọn si bọ wọn, ti nwọn si sìn wọn: nitorina li o ṣe mu gbogbo ibi yi ba wọn.