1 Sámúẹ́lì 16:5-11 BMY

5 Sámúẹ́lì sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà ni; mo wá láti wá rúbọ sí Olúwa. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì wá rúbọ pẹ̀lú ù mi.” Nígbà náà ni ó sì ya Jésè sí mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì pè wọ́n wá sí ibi ìrúbọ náà.

6 Nígbà tí wọ́n dé, Sámúẹ́lì rí Élíábù, ó rò nínú ara rẹ̀ pé lóòótọ́ ẹni òróró Olúwa dúró níbí níwájú Olúwa.

7 Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Má ṣe wo ti ìrísí rẹ̀ tàbí ti gíga rẹ̀, nítorí èmi ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Olúwa kì í wo ohun tí ènìyàn máa ń wò. Ènìyàn máa ń wo òde ara ṣùgbọ́n Olúwa máa ń wo ọkàn.”

8 Nígbà náà ni Jésè pe Ábínádábù, ó sì jẹ́ kí ó rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, “Olúwa kò yan ẹni yìí.”

9 Jésè sì jẹ́ kí Sámà rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì, ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, “Olúwa kò yan ẹni yìí náà.”

10 Jésè jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ méje rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì sọ fún un pé, “Olúwa kò yan àwọn wọ̀nyí.”

11 Nígbà náà ni ó béèrè lọ́wọ́ Jésè pé, “Ṣé èyí ni gbogbo àwọn ọmọ rẹ?”Jésè dáhùn pé, “Ó ku àbíkẹ́yìn wọn, ó ń tọ́jú agbo àgùntàn.”Sámúẹ́lì sì wí pé, “Rán ìránṣẹ́ lọ pè é wá; àwa kò ní jókòó títí òun yóò fi dé.”