7 Ọkùnrin kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ níbẹ̀ lọ́jọ́ náà, tí a tí dá dúró síwájú Olúwa; orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Dóégì, ará Édómù olórí nínú àwọn darandaran Ṣọ́ọ̀lù.
8 Dáfídì sì tún wí fún Áhímélékì pé, “Kò sí ọ̀kọ̀ tàbí idà lọ́wọ́ rẹ níhìn? Nítorí tí èmi kò mú idà mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mú nǹkan ìjà mi lọ́wọ́, nítorí pé iṣẹ́ ọba náà jẹ́ iṣẹ́ ìkánjú.”
9 Àlùfáà náà sì wí pé, “Idàn Gòláyátì ará Fílístínì tí ó pa ní àfonífojì Élà ní ń bẹ, wò ó, a fi aṣọ kan wé e lẹ́yìn Éródù; bí ìwọ yóò bá mú èyí, mú un; kò sì sí òmíràn níhìn mọ́ bí kò ṣe ọ̀kan náà.”Dáfídì sì wí pé, “Kò sí èyí tí ó dàbí rẹ̀ fún mi.”
10 Dáfídì sì dìde, o sì sá ni ọjọ́ náà níwájú Ṣọ́ọ̀lù, ó sì lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì, ọba Gátì.
11 Àwọn ìránṣẹ́ Ákíṣì sì wí fún un pé, “Èyí há kọ́ ní Dáfídì ọba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé,“ ‘Ṣọ́ọ̀lù pá ẹgbẹ̀rún tírẹ.Dáfídì sì pa ẹgbàarún tirẹ̀’?”
12 Dáfídì sì pa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí í mọ́ ni ọkàn rẹ̀, ó sì bẹ̀rù Ákíṣì ọba Gátì gidigidi.
13 Òun sì pa ìṣe rẹ̀ dà níwájú wọn, ó sì sọ ara rẹ̀ di aṣiwèrè ní ọwọ́ wọn, ó sì ń fi ọwọ́ rẹ̀ ha ilẹ̀kùn ojú ọ̀nà, ó sì ń wá itọ́ sí irungbọ̀n rẹ̀.