7 Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ásídódù rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Olúwa ti Ísírẹ́lì kò gbọdọ̀ dúró níbí yìí pẹ̀lú wa, nítorí ọwọ́ rẹ̀ wúwo lára wa àti lára Dágónì ọlọ́run wá.”
8 Nígbà náà ni wọ́n pè gbogbo àwọn olórí Fílístínì jọ wọ́n sì bi wọ́n pé, “Kí ni a ó ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn Ísírẹ́lì?”Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn Ísírẹ́lì lọ sí Gátì.” Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
9 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti gbé e, ọwọ́ Olúwa sì wá sí ìlú náà, ó mú jìnnìjìnnì bá wọn. Ó sì pọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà lójú, ọmọdé àti àgbà, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn oníkókó.
10 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ sí Ékírónì.Bí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ṣe wọ Ékírónì, àwọn ará Ékírónì fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì tọ̀ wá wá láti pa wá àti àwọn ènìyàn wa.”
11 Nígbà náà ni wọ́n pe gbogbo àwọn olórí àwọn Fílístínì jọ wọ́n sì wí pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì lọ: ẹ jẹ́ kí ó padà sí àyè rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” Ikú ti mú jìnnìjìnnì bá àwọn ará ìlú: ọwọ́ Ọlọ́run sì wúwo lára wọn.
12 Àwọn tí kò kú wọ́n pọ́n wọn lójú pẹ̀lú àrùn oníkókó, ẹkún ìlú náà sì gòkè lọ sí ọ̀run.